OTUN IMO NINU itAn - a r o s o D. O. FAGUNWA Olootu: r r r r r r Oluyemisi Adebowale Duro Adeleke > r r a Arinpe Adejumo UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY A te iw6 yii j£de l£ti il6-i?e ln i t r p u b l i c a t i o n s Gbogbo etQ ati a$e I6rf re j£ ti © Onimd-Edd Yorubd (Yorubct Studies Association of Nigeria) 2016 Enikeni ko gbodp da ohunkohun ko lati inu iwe yii ni onakona yato fun ilo ara tire laigba ase fun sise bee lati owp Egbe Onimo-Ede Yoruba. A le se iwadii ni: The Capstone Publications 22, Market Street, Shomolu, Lagos Tel: 08029749341/08072413959 Typesetting by: Temisayo Ventures, Faculty of Arts, U.i. Printed by: Agoro Publicity Company, Ibadan. ISBN: 978-34934 - 9 - 3 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY AKOONU Oju iwe Aworan Oloye D.O. Fagunwa iii Itan igbesi aye Fagunwa iv idupe v Qro isaaju vi Akoonu vii Ifaara ix 2 23 48 4. Ffff tipri igunni ni kese-inu edaniyan ti Abraham Maslow yiri itan-arosp D.O. Fagunwa wo 57 5. Ifedasesin ninu Itan-aroso Fagunwa 68 6. The writer as a moralists A study of Daniel Olorunfemi Fagunwa's Ireke Onibudo 76 7. Realism in D.O. Fagunwa's Novel: A case study of Ogboju Ode nfnu Igbo Irunmo/e 86 8. itagbon-inu ninu iwe Fagunwa 90 ISI KIN-IN-NI: IKONI, ITONI ATI ISEDANIYAN 1. Abuda adamo ikoni ninu awon itan-aroso D.O. Fagunwa 2. idanilekop ati asotele ninu asodasile D.O. Fagunwa 3. Fagunwa gege bi apanilerin-in onkowe alatinuda ISI KEJI: ASA, ERO ATI IGBAGBO YORUBA 9. Iha ti D.O. Fagunwa ko si ija ati ipari ija lawujo Yoruba ninu awon iwe itan-aroso re 10. Iha ti Fagunwa ko si eto idajo ni awujo Yoruba 11. Ifoju asa ifunniloruko adape wo awon oruko eda-itan Fagunwa 12. 116 oruko bi ifiwaweda ninu Adiitu Olodumare 13. Socio-semiotic interpretations of gift items given to some characters in Fagunwa novels: The perspective of Yoruba cultural beliefs 14. Isewadii imp-ilo-ami ero-ijinle ati Esin-abinibi ninu awon iwe itan-aroso 100 113 119 126 136 15. 16. 17. 18. 19. 20. 21. 22. 23. D. O. Fagunwa 147 Oruko Olodumare ninu ise Fagunwa 158 The Yoruba perception of the relationship between the living and the dead: Fagunwa's novel in cultural perspective 167 116 oogun fun idabobo ninu awon iwe Fagunwa 179 Representations of crime in selected novels of D. O. Fagunwa 186 Agbeyewo asa ninu awon iwe itan-aroso Fagunwa 196 Ijajagbara asa YoruBa ninu awon iwe itan-aroso D.O. Fagunwa 208 Asa ibile Yoruba ninu awon itan-aroso Fagunwa: Eko fun orile-ede Naijiria 218 Fagunwa ati eto orp-aje awujo Naijiria 235 Agbeyewo pro ife ati igbeyawo ninu asayan iwe itan-aroso Fagunwa 246 VII UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY I§I KETA: ISOWOLO-EDE ATI OGBON ISOTAN 24. More understanding of interaction of Yoruba bare nouns with kart, naa and nikarr. Evidence from novels of Fagunwa 262 25. Contextual analysis of focus constructions and content-questions in Fagunwa's Ogbdju ode nfnu igbo irunmole 282 26. Agbeyewo ona-ede nfnu awon iwe itan-arosp D.O. Fagunwa maraarun 296 27. Ilo-ede nfnu oro alaafia ati aawo ni'nu iwe itan-aroso Fagunwa 310 28. Eda-oro ati eda-isele ninu iwe Fagunwa, atokun fun wiwa oko olu eda- itan de ebute yfyanju 319 29. Agbeyewo awon itan aroso Fagunwa gege bi alo 328 KERIN: ORO TAKOTABO 30. Fagunwa gege bii onkowe asetofabo 341 31. Aworan obinrin nfnu iwe itan-aroso Fagunwa 350 32. Orogun sise ninu agbekale ise Fagunwa: Oju amuwoye awujo fun itupale kikun 362 33. Iwa obinrin ninu awon iwe itan-aroso Fagunwa 375 Akojopd Oruko Awon Onkowe 385 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY ORI KOKANDINLpGBpN AGBEYEWO AWON IWE ITAN AROSO FAGUNWA GEGE BI ALO AKANGBE Clement Adeniyi ifaara Yoruba bo won ni "Ajanaku kojaa mo ri nnkan firi, bi a ba ri erin ka kuku so pe a ri erin", oloogbe Danieli Orowole Fagunwa (1903-1963) kuro ni opije laarin ohkpwe itan arose Yoruba. itan aroso marun-un ptoptp ni Fagunwa ko: Ogboju Ode Nfnu Igbô Irunmak (Ogboju) 1938, Igbo Oiodumare (igbo) 1949, ireke Onfbudo (ireke) 1949, irinkerindc Nfnu Igbo Eiegbeje (irinkerindo) 1954 ati Adiitu Olodumare (Adiitu) 1961. Yato si awon wonyi, Fagunwa tun ni awon ise mliran bi irinajd: Apa Kini (OUP 1963); itan Oloyir (OUP 1964); Fagunwa, Delano, I.O. ati awon yooku, Asayan itan (Nelson 1959); Fagunwa ati Lasebikan, OJo Asotan (Heinemann 1964); ti a te jade leyin iku re. Fagunwa ati L.J Lewis ni 6 jo ko Tafwd ati Kehinde iwe Kirnf, (6llP 1948); Tafwd ati Kehinde iwe Keji (OUP 1950); Tafwd ati Kehinde iwe Keta (OUP 1950); ati Tafwd ati Kehinde iwe Kerin (OUP 1951). Awon iwe itan aroso maraarun ti Fagunwa kg ni yoo je wa logun ninu pepa yii nibi ti a 6 ti fi oju alo wo awon itan inu iwe naa. Abala merin ptoptp ni a pin pepa yii si. Ifaara ni 6 siwaju, Alo Yoruba, Tipri itatare- ise, Afiwe Ise Fagunwa ati Alo, ati Iyapa Ise Fagunwa si Alo ni 6 tele ara won. Agbalogbabp ni a fi kadii ijiroro wa. Alo Yoruba Alo je okan lara litireso alohun Yoruba. Abe ewi arangbo gan-an ni a to alo si, awon wonyi ni a mo si alabuda, ti Olatunji (1984:8) pe ni "feature types". Gege bi Opadotun (1994:1) ti so, "Alo je orisi litireso alohun Yoruba kan ti a maa n 16 fun idaraya, igbadur ati ikoni-lekpp" Alo pin si orisii meji; apamo ati apagbe. Bi 6 tile je pe alo apamo ni c maa h se atokun fun alo apagbe tori pe a maa fi n side ni, ise ti alo apamo n se ju ti atona lasan yii Ip tori pe aditu gbaa ni ede re. Ni ti ero Opadotun, "won maa n lo alo apamo gege bi ifaara fun alo onitan. Won maa n 16 6 fun pipale okan awon olugbaloo mo sile de alo onitan. Won tun maa n 16 6 titi ti awon egbe alalpo kan yoo fi sa oju jo tan" (1994:1). Eyi fi han pe ise iside ni alo apamo wa fun. Bi ise iside re tile to 6 si ipo yepere, atari ajanaku ni ede re, eyi ti ki i se eru fun ompde. Ihun re pelu fakiki, asunki eko ijinle ni, 6 si n se afihan ero Yoruba nipa ayika won. N je bi alo apamo ti 6 je akede lasan fun alo apagbe ba le tewon bayii pelu iwulo ti 6 ga, a ko saimo pe laarija ti alo apagbe yoo gadabu! Orisii keji ni alo apagbe eyi ti Ogundeji (1991:26) pe ni alo onitan. Gege bi 6 se so, "alo onitan yii naa ni a mo si alo-apagbe, papaa julo laarin awon Oyo Yoruba". Ni ti Opadotun, Alo onitan ni itan alohun ti ki i se ootp sugbon ti 6 da lori eniyan tabi eranko tabi eye tabi iwin ti a so lati ko pmode ni eko tabi lati fi idi abajo kan mule. Iru alp bee le ni orin ti UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY yoo ni egbe, 6 si le sai ni orin de ibi pe yoo ni egbe." (1994:1) A fi ara mo erd Ogundeji ati Opadotun pe 6 san ki a lo alo onitan dipo alo apagbe niton pe alo onitan kenu 6 si gbooro ju alo apagbe Ip. Fun idi eyi, alo onitan ni a 6 se amulo ninu ise yii. Alo onitan je ona ti Yoruba maa n gba lati ko awon prngde ni eko, eyi ni Yoruba se maa n so pe alo ni tpmode, owe ni tawon agba. 6 je ona imutanlo lati fi isele inu itan bee ko awon omode logbon. ijapa tiroko okp Yannibo, olpgbpn ewe, ni 6 saba maa h je olu itan alo Yoruba. Ninu isesi re, a maa fi ogbon alumpkoroyi re de awon eda itan yoku mole sugbon, ika a maa ka onika, isu ika re a maa ta fun un je, a si maa ti ipa bee gba ijiya ti 6 to. Ko si ise eniyan kan ti awon eda itan wonyi kii se. Amo sababi gbogbo iwonyi ni lati ko omode ni eko nipa bi a a se huwa ni awujo. Apaalo ni 6 maa n pa alo, awon omode ni 6 si duro bi olugbo. Apaalo ni 6 maa n ti ipase alo re waasu fun awon omode nipa fifi pkan-6-jpkan isele inu alo re se kilokilo iwa nipa suuru, iteriba, iforiti, itepamose, isotito, ikaaanu, iranlowo, ife, ipamora, isoore, abbl. Agbekale Alo Alo onitan Yoruba ni eto gunmo ti 6 maa n tele, ifaara ni 6 maa n bere alo onitan, eyi ni Ogundeji (1991:26) pe ni isorongbesi kekere laarin apalo ati olugbo. Apalo ni agbalagba ti 6 n pa alo, awon omode ti 6 n teti si apalo yii ni olugbo. Apeere niyi: Apaalo. Alo o Olugbo. Aalo Apaalo. Alo mi da furugbagboo Olugbo. Ko ma gbe agbo omp mi Ip Apaalo. Alo mi da lori ijapa tiroko oko Yannibo ati Iya Elepa. Onsiirisii ni ifaara yii je, 6 si yato diedie lati adugbo kan si omiran. Ajosepp a maa waye laarin awon ohun abemi ati alailemii ninu alo onitan. Apalo a maa da oniruuru ogbon lati mu itan re dun ki awon olugbo re si gbadun re. A maa lo ede awada ati pro ti 6 panilerin-m, a maa se isinje awon eda itan bi i ki 6 maa ranmu soro lati sin ijapa je. Bakan naa ni apalo maa n fi orin bp alo laarin, eyi si maa n je orisun idaraya gbaa. Awon omode a maa gbe orin yii, won a maa patewo si i, won a maa lulu si i, won a si maa jo si i pelu. Laarija alo onitan ni idanilekoo iwa. Yoruba se agbekale alo lati da awon omode lekoo nipa iwa pmoluabi, lati mo rere yato si ibi ati lati se afihan awujo Yoruba fun won. Idi niyi to fi je pe ni ipari alo, apalo a maa se afayo eko ti alo yen ko wa. Bi apeere: itan yii ko wa pe ki a ma maa jale, itan yii ko wa pe ki a ma maa se ojukokoro, itan yii ko wa pe ki a ma maa hu iwa ika, abbl. Gege bi Ogundeji ti woye, "nigba miran ni'pari itan bee apalo le pe akiyesi si idi abajo ti 6 suyo ninu itan" (1991:27). idi abajo bee le je idi ti eye akoko se n fi enu so igi kiri, idi ti elede se n fi imu tule kiri, idi ti eyin ijapa fi ri kangun kangun( abbl. Igunle ni 6 maa n tele afihan eko inu alo, oun naa si ni igbese ti 6 gbeyin ninu alo pipa. igunle alo, gege bi ifaara, maa n yato lati adugbo de adugbo. Bi apeere: Apaalo: idi alo mi re e gbangbalaka 329 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY idi alo mi re e gbangbalaka Ko gborogbo je ko ma se gbobi je Niton orogbo ni i gboni saye Obi ni i gbo won sorun Bi mo ba puro Ki agogo enu mi ko ma dun leemeta Sugbon bi n ko ba puro Ki agogo enu mi dun leemeta 0 di po 0 di po 0 di po 6 ro nbi 6 ro Olugbo: 6 ro baba (Ogundeji, 1991:27). Apeere miiran niyi: Idi alo mi ree gbangbalaka Idi alo mi ree gbangbalaka Bi mo ba parp Kegun-un ogede gun mi lese Ko ma ma yo Ki n teba Ki n si robe je e Kigba omp 6 gbe mi sin. (Opadotun, 1994:7). Koko-pro se pataki ninu alo. Gege bi a ti so siwaju, idanilekop iwa ni olubori koko-pro alo onitan. Se isaluwala ologbo, ogbon atikeranje ni. Gbogbo afojusun apalo ni lati ko awon pmode ni eko. Apalo, a maa yonbo iwa ompluabi bi i siso otito, sise iranlowo fun enikeji, nini ife, titepamose, sise aanu, nini ifarada, abbl.; a si maa bu enu ate lu sise ole, sise imele, nini okanjuwa, sise ojukokoro, sise ofofo, ole jija, iro pipa, He dida, inu bibi, ika sise, ikoriira, owu jije, gbigberaga, hihawo, abbl. Awon koko-pro amugbalegbee tabi aspmogbe ti a fi maa n gbe eko iwa kale ni esan, ija orogun, ati idanwo; Idi-abajo ni koko miiran ti alo onitan maa n da le lori. Ihun itan alo onitan je eyi ti 6 Ip taara, ti ko ruju, ti ko si fa ppn-on-na. Agbekale alo ko dabi ti itan aroso tabi ere onitan ti 6 ni ibere ninu eyi ti a ti n se afihan awon eda itan; leyin eyi ti a 6 bere si ri ifarakinra ati ikolura awon eda itan, eyi ti yoo bi rukerudo, ki 6 to wa de ikorita yiyanju ninu eyi ti onikaluku eda itan yoo ti gba idajo ti 6 to si i. Awon abuda ti 6 hande ninu ihun alo Yoruba ni asetunse isele, isele ayisodi ati ayipada igba (Ogundeji, 1991 : 33-36). Asetunse isele je abuda baraku fun opo alo onitan Yoruba ninu eyi ti isele kan naa yoo maa waye leralera. Irufe isele bee a si maa ni ayorisi kan naa ni gbogbo igba ki 6 to wa di pe yoo ni ayorisi ti 6 yato ni igbeyin-gbeyin. Asetunse isele a maa mu ki itan gun. Irufe alo onitan bayii a si maa je apagbe ninu eyi ti orin, ilu ati ijo sodo si. Apeere ni alo ijapa ati Iya elepa, omiran ni ijapa ati Iya alakara. Ninu alo ijapa ati Iya alakara ni Ijapa ati omp re ti maa n da omp alakara Iona ti 6 ba n kiri oja re Ip si abule keji. ijapa ati omp re yoo fi ewe ogede gbigbe bo ara, won yoo si be sona lojiji bi i ahjonnu lati 330 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY derii ba omp alakara. iberubojo ni lyen yoo fi da oja re nu ti yoo si sa asala fun emi re. Ijapa ati omp re se bayii fun igba pipe ki owo Osanyin elese kan to ba a. isele ayisodi a maa waye nigba ti ayorisi igbese ti eda itan kan ba gbe ni akoko ba ni ayonsi ti 6 yato si ti akoko igba ti eda itan yen tabi eda itan miran ba gbe iru igbese bee. Gege bi alaye Ogundeji, Isele ayisodi maa n waye ninu alo onitan nigba ti ayorisi igbese ti eda itan kan gbe ba je ayisodi tabi odikeji ayorisi iru igbese kan naa ti eda itan miiran tabi eda itan kan naa yen ti koko gbe. (1991:34). Apeere eyi wopo ninu itan olorogun ninu eyi ti iyawo yoo ti se oriire ti yoo si bun iyaale ninu re, amo eyi ko ni te iyaale lorun, oun naa yoo si fe gbe iru igbese ti iyawo gbe amo dipo oriire, ifooro ati idaamu ni yoo ba pade tori pe oun ko ni le ni iru suuru ati ifarada ti iyawo ni. isele ayisodi yii a maa pin itan si abala meji ogbpogba ninu eyi ti ire ati ibi yoo ti foju han. Ayipada igba ni abuda keta ti 6 hande ninu alo onitan. Eyi maa n waye nigba ti eda itan kan ti 6 la ti 6 lu ni ibere itan ba wa di akusee ati atoroje ni ipari itan. Eni ti 6 se alaini ni ibere itan si le wa di olprp ni ipari itan. Isele alo onitan ko bowo fun akoko rara, bee si ni ko bowo fun ibudo pelu. isele alo le waye ni aye 6 si le sele ni alede orun. Osan ati oru ko se idiwo kankan fun isele alo, ogbpogba ni osan ati oru je. Ewe, ko si aala laarin alaaye ati oku, won a jo maa ba ara won se. Bee ni orun ko jinna si aye, ara aye le tara Ip si orun ki 6 si pada were, bee ni ara orun naa le da kan wa saye ki 6 si tun pada. Irufe iha ti alo onitan ko si ibudo isele ati akoko isele yii a maa je ki isele meriiyiiri rorun lati sele. Ifiwawpda yii tun bo mu ki abuda meriiyiiri ta ekan mole daadaa ninu alo. Nipa ilo ede, yato si awon gbolohun iside ati ikadii ti a ti soro ba, ilo ede alo rorun. Ede ojoojump, ede ti ko farasin ni a maa n ba ninu alo onitan nitori pe awon ewe, awon ipeere ni olugbo alo. Fun idi eyi, gbolohun kekeke, gbolohun taara, ati ede ti 6 rorun fun ompde lati mo ni apaalo maa ri yan laayo. Owe, ijinle pro, akanlo ede, ati ede ikasi ko wopo ninu alo. Awon abuda ti a ti salaye wonyi ni 6 je baraku fun agbekale alo onitan Yoruba. Awon Olu Eda itan Fagunwa Bi 6 tile je pe awon iwe itan aroso re maraarun yato si ara won, sibe abuda ti 6 hande ninu opo itan re ni sise agbekale olori eda ifan gege bi akoni, arewa, plogbpn, oloogun ati alaseyori, 6 je akanda eda ti yoo setan lati fi emi re la ewu ninu irinajo lati mu idagbasoke ba ilu re. Eyi le je lati Ip gba nrikan pataki ti ypp fun Oba ilu won ni alaafia ati aasiki lati odo oba ilu Oke Larigbodo {Ogboju),̂ irinajo Ip si ilu itanforiti lati Ip gba nrikan ti oba ilu Alupayida yoo 16 fun aisan re wa (ireke), tabi lilo si Oke ironu lati Ip ka eso igi ironu wa fun oba ilu won {Irinkerindo). Olu eda itan yii ki i da nikan Ip si irinajo bee, a maa ni isompgbe ati oluranlowo. ispmogbe wonyi le je awon ogboju ode bi Kako, Imbdoye, Olohun-iyp, Elegbede ode, Efoiye ati Aramorida Qkunrin (Ogboju); alagbara ati pjogbon bi i Erpokan ati Kumofehinti {Ireke)) tabi oniruuru eda pataki bi Aiyederu-eda, Inulaiyewa, Ewe-eiye (babalawo), Olojumajele, Kumpdiran, Filasaiyepp, Iberribe Olokunrun, ati ireke (onifere) (irinkerindd). Ninu irinajo yii, olu-eda itan a maa koju isoro ati wahala, opo ninu awon ispmogbe re le jase latari iyonu wonyi amo ninu ofii oun olaa, omp paridpro tire a maa 331 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY gbo. Bf isoro yif ba tile fe koja agbara olu eda itan yif, iranlowo a maa wa nf orisif ona yala kf baba tabf iya re tf 6 ti di oloogbe yo si i lati ran an lowo, tabf arewa obinrin bf Iranlowo (Ogboju) ati ifepataki (ireke). Nf igbeyin, owo re yoo te ohun tf 6 wa Ip si irinajo, yoo si pada sfle pelu ayo. A maa ti ipase aseyorf yif di glola ati plpro, koda a maa joba pelu gege bf imoyi akitiyan oun laalaa re lati odd awon ara ilu. Nf ede kan, alalobo ni olu eda itan wonyf maa n je nfnu irinajo won. Laise anfanf, abflpje ni Fagunwa nfnu asa ati ise Yoruba. Fun idf eyf, ko yani lenu pe o fi ilana alo se agbekale awon itan aroso re. Gege bf awo nfnu Iftfreso alohun Yoruba, 6 fi imp abalaye re da omi Iftfreso apileko lati polongo imp abalaye yif kf 6 si ti ipa bee gbe imp otun jade. Nf sfse eyf, Fagunwa ki f sadeede gbe Iftfreso alohun wo inu feremu ti apileko lobpro sugbon a maa se amulo re gege bf eroja adfdun ise atinuda re kf ogo ati ete ise atinuda bee le munadoko daradara. Laarija eyf ni pe iru ogbon yif a maa mu kf ise onkowe je ise tf 6 ye kf 6 je fun awujo, idf niyf tf Fagunwa se lo alo bf fere lati polongo ise re fun omp araye. irele (1975:79) naa jerif si eyf pe: ...his narrative technique flows directly out of the oral traditional; at the same time, it is evident that he strove, even with noticeable strain, to get beyond the limitations of the tradition in the context of an extended literary medium. itokasf yif fi erf han pe onkowe kan lo alo bf gbohungbohun fun ise re ni, ise re loorin ju alo Ip. Loooto, alo hande pupo nfnu ise Fagunwa amo 6 se pataki lati yan an pe alo nikan ko ni orfsun ise wonyf. Opo ise ni onkowe tatare sfnu itan re kf 6 le ladun kf 6 si loyin. Awon orfsif ona meta gboogi tf Fagunwa ti se afayo (eroja) ni Iftfreso ile Gfrfki agbogoyo, Iftfreso Geesi ati nfnu itan alo ile awon Arabu (Adeleke, 2011:32). Amo se ohun tf 6 ba wuni nf po loro eni, pro alo ni 6 je wa logun, oun ni a 6 si se agbeyewo ffnnfffnnf nfnu ise yif. Tiori itatare-ise lati inu ise kan si omiran Tfori Itatare-ise lati inu ise kan si omfran tf a mo sf "Intertextuality" je eyf tf Julia Kristeva, omp ile Faranse tff se onfmo nfpa imp eda-ede, gbe kale nf odun 1966. Julia Kristeva fi idf ero re mule pe ko sf ise Iftfreso kan tf 6 da wa gedengbe funra re ati pe ise kookan ni 6 kun fun orfsifrfsif awon ise mifran. Otfto pro tf ko see ja nfyan ni pe se ni akoonu gbogbo ise Iftfreso alatinuda ko ara won bf ewon, tf won si wo inu ara won bf eran tif wo inu egungun. Idf abajo si ni pe gbogbo ise tf 6 ti wa saaju ni 6 maa n nfpa lorf ero ati ogbon atinuda onkowe tf 6 ko ise tuntun jade. Onkowe le mppnmo se amulo awon abala kan lati inu awon ise ti isaaju, 6 si le seesi mu won 16 laije pe 6 tile fura rara. Gege bf iwoye Hofele (1997:69) nfnu Adeleke (2011:10), "Nf kukuru ede, 6 se e se kf awon eda itan ati onsotan farahan nf orfsifrfsif ona erero tf a ti difdi potobo kale Iona tf idamo re yoo fi yapa sf irfsf tabf iseda ipile re". Adejump (2011:209) naa fi ara mo ero yif. 6 gba pe ajosepo tf 6 jinle wa laarin Iftfreso alohun ati apileko nftorf awon mejeeji jo maa n fi otun ati osi we ara won ni. Gege bf 6 ti wf, "there is inter-relationship between the oral and the written traditions because they constantly nourish each other". Gege bf ero Umberto Eco nfnu Haberer (2007:57), 332 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY [ It is not true that works are created by their authors, i Works are created by works, texts are created by texts, all together they speak to each other independently of the intentions of their authors. Ki i se dtito pe awon onkowe ni 6 n seda awon ise won. Awon ise 16 n seda ise, iwe 16 n seda iwe, won a si maa fohun sira won lapapo yato si erohgba ti onkowe. Ero Eco yii fi idf re mule pe ajaso ati ajaro inri dun ogbon ti onkowe ti ni lati inu awon oniruuru iwe ti 6 ti ka ati awon Imp Ipkan-d-jpkan ti 6 ti nl seyin ni 6 maa h parada di iwe gege bi isu tii parada di iyan ti agbado sii parada di eko yangan. Amo sa o, imp ati ogbon inu iwe nikan ko ni onkowe maa n tatare si inu ise tuntun o, gege bi Eliot naa se so ninu Haberer (2007:61), (Intertextuality is) a text's dependence on prior words, concepts, connotations, codes, conventions, unconscious practices, and texts. Every text is an intertext that borrow, knowingly or not, from the immense archive of previous culture. itatare-ise je igbarale ise kan lori awon pro asoti, aba, ijasi, ami, asa, ise baraku, ati akoole. Gbogbo iwe 16 je akojo iwe ti a ya lati inu ibu aka asa, yala a mppnmo tabi a ko mo. Oro Eliot yii 16 se eri pro pe ko si aala kan pato si orisun imp ti onkowe le fi tatare. 6 le je lati ara imp ti 6 bu mu ninu asa ati ise, itan, orin, ewi, aalo, esin, oselu, okowo, abbl. Adeleke (2011:19 - 34) fi idi pro mule pe itatare-ise pinmirin sinu awon iwe Faguwa, bi 6 ti kun inu awon iwe itan aroso re maraarun naa ni 6 farahan pupo ninu awon ise re yooku. Bi 6 ti jeyo ninu Taiwo ati Kehinde (iwe kinmnf sf ikerin) naa ni 6 hande ninu Ojo Asotan ati itan Oioyin. Adeleke toka si orisii ona meta ti itatare-ise fi waye ninu awon iwe itan aroso Fagunwa. Awon ona wonyi ni itatare litiresp alohun sinu ise litiresp apileko, titatare ise inu iwe kan si omiran, ati titatare batani ise apileko ile okeere. Afiwe Ise Fagunwa ati Aio Ko si okan ninu awon iwe Fagunwa ti amulo awon abuda aio wonyi ko ti jeyo. Orisii ona tile ni eyi gba waye. A ri ibi ti Fagunwa ti gbe odidi aio bp inu itan re, eyi si waye Iona ti 6 je pe gedegbe ni iru aio bee han si onkawe. Bi apeere, itan Ajantala ninu dgbojuyk eyi ti ko farasin rara. Yoruba a maa so itan abami omp ti 6 ti bere si se ise agba ni kete ti won bi i tan. Janduku ati onijagidijagan omp ni. 0 ti kekere ya pokii. igba ti wahala re su awon ara ilu ni won pa imp po lati dogbon mu un jade ni ilu, won si ke e sile ninu aginju. Kin ni 6 de inu aginju si, pakaleke re ko je ki awon eranko gbadun, 6 si fi iyonu re tu agbo won ka. Yato fun eyi, itan Ologbo ijakadi ati ekun {Irekd) paapaa je afayo lati inu aio. Aio yii se afihan bi ijapa se fi ogbon tan oni pe oloola ni dun, dun si setan lati kg 333 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY awon omo re ni ila ki won baa le ni anikun ewa. Inu oni dun, 6 si fi gbogbo ara gba pe ki ijapa ko awon omo oun ni ila. Amo si iyalenu, nise ni ijapa bere si nf pa awon omo oni ni pkpokan ti 6 si ri fi won je iyan. Omo kan soso ti 6 ti ko ni ila ni 6 bere si ni fi han oni lati okeere ni ojoojumo. igba ti 6 si setan atilp, 6 tun pa abikeyin oni yii naa, 6 si fi ese fe e. Amulo awpn alo wonyi ni odidi segbe pro wa pe Fagunwa fi alo se ategun awon itan aroso re. itatare-ise ni eyi je, eyi si je apeere itatare litireso alohun sinu ise litireso apileko. Akiyesi kikun nipa awon koko ti a maa h ri toka si ninu itan Fagunwa ko fi ibi kan yato si ti alo eyi ti 6 fihan pe ijora wa laarin won. Bi apeere, opo alo a maa da leri bi ijapa se koju isoro ati ogbon ti 6 ta lati yo kuro ninu isoro yii. igba miiran, 6 le kuna ninu isoro naa ki 6 subu. Olu eda itan Fagunwa naa le ko si takute ota, ki o si ti ipa eyi bo sinu isoro. Koda iru isoro bee le ju agbara re Ip ki 6 si je pe oto ni ibi ti iranlowo re yoo ti wa. Ninu ireke, Arogidigba fi oju ireke Onibudo ri mabo. idanwo meta ptopto ni 6 gbe ko 6 laya. 6 ni ki 6 ko ile peteesi ni oojp, ki 6 gbin isu ki 6 ta ni oojp, ki 6 si ba ewure iberu ja; ko si eyi ti ko ka a laya ninu idanwo wonyi sugbon iya re ti 6 ti di oloogbe yo si i, 6 si tan isoro re. Inu alo ni oku ti maa n pada di alaaye ti yoo si se nnkan iyanu. Bakan naa ni Ogongo baba eye tii se olori awon eye fi oju Akara-oogun ati awon ogboju ode yooku han eemo ninu irinajo won si Oke Langbodo (ninu Ogboju). iyonu ti Olowoaiye omo Akowediran ati awon emewa re ri laafin Ojola-ibinu tii se olori ejo aye gbogbo pelu ko se fenu so (Igbo). Koko miiran ti alo maa n safihan re ni idi abajo. Alo yoo so ohun to se igun to fi pa lori ati oran to se akala to fi yo gege lorun. Bi ori obo se pa, ti idi re si huru, ohun ti 6 n mu akoko maa fi enu so igi kiri, ti ologbo ati ekute si di ata oun oju, abbl. ni alo yoo so hulehule re. Abuda iwa alo yii naa kii gbeyin ninu iwe Fagunwa. Ninu Ogboju bi apeere, a ri alaye nipa ohun ti 6 mu iku je dandan fun awa omo adarihunrun. idi abajo yii naa, gege bi Fagunwa se fi han, ko ju pe lati igba ti a ba ti bi omo ni awon malaika ode orun yoo ti gbe ewu iku wo 6 ni ode orun ki 6 to mu irinajo re pon si ode isalaye. Eyi naa ni 6 si fa a to fi je pe bi 6 ti wu ki a pe to laye, akuko gbodo ko leyin omokunrin ni ojo kan. Ninu iwe yii kan naa ni a ti ri idi bi ewure se di eran osin ni ile. Bi a ba wo 6, lati igba de igba ni Fagunwa ti maa n se ayaba, ayaba yii si le je ti iwaasu. Gbogbo iwaasu Fagunwa ki i da lori koko pro miiran ju otito, iforiti, itepamose, oju kokoro, ibinu, abbl. gege bi 6 se maa n wa ninu alo. Alo yoo yonbo iwa rere, yoo karamasiki iwa ompluwabi, otito, inu rere, ife, ododo ati iranlowo; yoo bu enu ate lu ole jija ati ipaniyan, yoo si tenbelu iro pipa, igberaga, rikisi, isote, owu jije, tembelekun ati awon iwa wononni ti 6 tako ofin Olorun. Irufe eko wonyi ni alo maa h da le lori, bee gan-an naa ni 6 si se ri ninu awon iwe Fagunwa. Se laarija alo ni idanilekoo iwa ati kiko omo ni ede, bee gele ni afojusun Fagunwa ri. Olubori ete re ni sise idanilekoo, ki i si i kere lati se eyi bi anfaani re ba ti si sile. Fagunwa ni 6 duro bi apaalo nigba ti awon ogunlogo onkawe re je olugbo. Se ohun ti 6 ba johun ni a fi i we ohun, eepo epa jo posi eliri, adigbonnaku jo imi ahun; ijora ti 6 ga ju Ip ti a tile le tokasi pelu iwe Fagunwa ni ihun tabi agbekale alo onitan. Isori meta ptopto ni a le pin alo si ni erefee. Iwonyi ni ibere, aarin ati ipari. Apaalo a maa se ifaara ni ibere, leyin eyi ti yoo si na enu mu itan re so ki 6 to wa se alaye orisii eko ti iru alo bee ko wa ni ipari. Fagunwa a maa to ara re si ipo asotan, a si maa side itan re gege bi apaalo ti i se fun awon olugbo re. Eyi a maa jeyo ninu awon ipede re bi"Enyin ore mi" {Igbo) ati {ireke), "Enyin omo enia" {irinkerindd). Ninu ifaara 334 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY re ni 6 ti maa n se afihan asotan leyin eyi ni yoo si mu kf ipade waye laarin asotan ati oun funrare (Fagunwa). Asotan yif le je ode akikanju ti 6 n so itan ara re (Ogboju) tabi ki 6 maa so itan ti baba re ti 6 je alagbara (Igbo). 6 tile le je okunrin lasan ti onkowe ko naani {Ireke). Iru itan wonyi a maa side gege bi itan igbesi aye akoni kan ti o mu irinajo yif pon fun idf kan tabi omiran, ninu irinajo yif ni yoo ti maa ti ori iyonu ati isoro kan bo si omiran nipa pipade orfsif abami eda, kerekere; itan naa a si ti ori isele oju aye bo si ti meeriyiirf. Ninu Ireke, a ri onkowe ti 6 n salaye bi oun ati aburo re ti se n Ip si oko ati bi odo se kun eyi ti 6 mu ki 6 da aburo re pada sile ti oun si we koja odo amo si iyalenu, eda kukuru kan oloju kan ni 6 ba ni iha keji odo yii. Lehin eyi ni iru awon eda abami bawonyi meje mu un ni igbekun. Bayii ni itan yii bere si feju sii pelu pkan-6-jpkan isele kayeefi, kerekere, itan ti 6 bere gege bi isele oju aye di ti meeriyiirf. Meloo ni a 6 ka ninu eyin adipele ni pro Fagunwa ati awon isele aramonda inu itan re, ko si okan ninu awon itan re maraarun ti awon isele aramonda ko kun fofo. Koda isele wonyi ni 6 fi n se opomulero itan re tori bi a ba yo won kuro ninu itan kopkan nnkan yoo tan nile. Ninu Ogboju, Akara-oogun se alabaapade orisii eda iberu bi Ebora inu awusa, Agbako, Kurembete ati Tembelekun. Oun ati awon akoni yooku se abapade Eru, Ogongo fi oju won ri atalaata baba alaruba nibi ti won ti kan eemo lowp eranko nla, awon Iwin ile ati Were orun. Gbogbo awon eda wonyi ni 6 ni abuda iyanu. Agbako ni oju merindinlogun, Kurembete je iwin buruku ti 6 ni ori meji ati iwo meji pelu oju nla kan ni igba aya re, seyeseniyan ni Ogongo tori pe ori eniyan ni 6 ni, awon iwin ile po bi baba esua, Were orun si burn bi esu. Inu alo ni a ti maa n ba orisii nnkan aramonda bawonyi pade eyi ti a maa n 16 lati le mu iyanu ba awon omode ki eko itan naa si le duro sinsin ni ookan aya won. Isele ijoju yii ko f)in si inu Ogboju nikan, 6 tile kamomp ninu Igbo Olodumare. Olowoaiye se abapade Esu kekere ode ni Aginju idakerpro. Eda buruku ni ebora yii, inu ogan ni 6 si n gbe. Bi Olowoaiye ti so, "ebora kukuru bilisi ni, 6 maa n gbe eru pasan kiri titi aiye gbogbo" (o.i. 12). Apejuwe ti Olowoaiye se nipa ebora yii lasan tile to lati pa ojo ku ki 6 si mu alagbara maa to si sokoto. Yato fun Esu Kekere Ode, ode aperin tun woya ija pelu Anjonnu iberu tii se Onibode Igbo Olodumare, oju re ri mabo lori igi ti 6 ha si ki Qlorun to yo 6, bakan naa ni 6 si ko sinu pakute Ojola-ibinu tii se olori ejo aye gbogbo. Ireke Onibudo ni tire ba Ewure iberu ja, 6 pa Ejo apanirun ti o fe gbe Ifepade mi, ikun imu otun re si bo si ti osi ki oun ati awon eniyan re to gun Oke Hilahilo de oke. Elegbara se sia fun Irinkerindo, won se alabaapade igberaga-ibanuje ati Ahondiwura aya re, oju won si ri to ki won to ka eso igi ironu. Aditu paapaa ko salai foju wina ni ilu ifehinti leyin ti 6 si jajabo tan, bi 6 ti n ba ejo ja ni o n ba oni ja, oju re ri iponju debi pe ailenikan je ki 6 pe aja ni awe nipa siso eranko di ore. Fagunwa gan an alara tile jerii si awon isele aramonda ati ohun kayeefi wonyi nigba fi 6 n sapejuwe Igbo Olodumare. 6 ni. Ibe ni awon eiye ti nfohun enia, ti awon eranko nta oja fun ara won, ti ogunlogp igi ko ni gbongbo sibesibe ti ara won tutu nini ti ewe won si dudu mirinmirin. Ekute tobi ju okete, igbin si tobi ju ijapa, ninu Igbo Olodumare. Awon ebora alagbara ati awon jagidijagan anjonnu ni nwon si njumo se are po beni awon ejo alakori gbogbo a tun ma deruba awon ode nitori ibe ni ile olori ejo aiye gbogbo, ojola-ibinu ni oruko re nje. (o.i. 8-9). 335 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY Nje alaye onkowe yif funra re ko ti kogoja pe isele abami ni 6 kun inu awon iwe itan re fofo gege bf 6 ti maa ri ri nfnu alo? Leyin tf Fagunwa ba ti na igbara na igboro tan bayif nfnu pkan-6-jpkan itan re ni yoo wa mu ise wa si iparf. Nf iparf yif ni 6 ti maa ri fi enu pro re jona tf yoo si gba orikawe ni iyanju Iori koko tf 6 je oluborf tf 6 fe kf 6 dimu. A maa fi ye orikawe pe ko si eda kan tf ko nf la laasigbo kpja ninu aye tori oju tf ko rf pipon ina, tf ko rf rere oorun ko le rf ohun to ri dan yinrin bf ide, tori naa kf gbogbo mutumuwa sinmedo. 6 la a mole nfnu dgboju pe ko sf eni tf ko nf Oke Larigbodo tire lati Ip. Bayif naa ni 6 se mu pro re wa sf opin nfnu Igbd Olodumare. Mo fe ki gbogbo enia fi i si okan pe ko si eniti ko ni Igbo Olodumare tire lati Ip ninu aiye, Igbo Olodumare ti enikan yato si ti enikeji ki Olodumare jeki olukuluku ti Igbo Olodumare tire de laini ipalara. Isoro ti a ko lagbara gbe ki Qlorun Qba mase gbe e ka wa laiya. (o.i.163). Se ete Fagunwa ni lati ko awon onkawe re logbon, a kuku maa te eyf mo won letf nf iparf itan re kf eko wonyf le duro sinsin lokan won. Eyf ko si yapa si ilana alo naa nfbi tf apaalo ti maa n fa komookun pro re yo fun awon olugbo re nf ipari alo re. Bamgbose (1974:9) naa jerf sf eyf. The moral intention that runs through Fagunwa's novels is perharps the most important single element in them. The author sees himself as someone who must teach and impart moral lessons, and his readers are expected to take these lessons to heart and learn from the incidents in the novels. Bf Fagunwa ti ri fi orfisf isele, yala nfnu ojulowo opo itan re tabf ayaba, koni nf eko naa ni 6 ti ipase awon eda itan re tf 6 gba inu aginju kan koni logbon. Opo awon eda itan re ni 6 duro gege bf ibudo eko. Apeere eda wonyf ni: Agutan inakf, ibanuje isale, Baba Onfrugbon yeuke (Igbo), Gprigosu-takiti, Afyederu-eda, Ibembe-plpkunrun, igbfn enia, Ifepataki, Omugpdimeji, Omugodimeta, itandiran (irinkerindd). Onkowe ti ipase awon eda itan re koni nf orfsif eko. Irele (1975) tun toka sf eyf. The significance of his work is thus inherent in the symbolic framework and connotations of his novels. A simple but valid interpretation of the pattern of situation in his novels suggests that his forest stands for the universe, inhabited by obscure forces to which man stands in a dynamic morals and spiritual relationship and with which his destiny is involved, (p. 81-82) Liarfja ise re hande nfnu agbekale ati Ijasf awon itan re. itump tf awon isele inu itan re nf, tf ko se e ja nfyan, ni pe aginju re duro fun ile aye nfnu eyf tf onfruuru ati onfwaawa eniyan ri gbe tf won si jo ri nf ifarakfnra nfnu ara ati emf lorf eyf tf ayanmo won da le. 336 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY Ni aise aniani, Fagunwa gege bi onkowe ri fi ise ona re ya aworan awujg re sita kedere fun aye ri yala fun iyoribo, ikan-saara-si, ibu-enu-ate-lu, fun ibawi, tabi fun atunse. Gbogbo ilakaka onkowe ni lati mu ayipada to dara ba awujo re ki igbayegbadun le wa, ki idagbasoke si le to awujo lowo. Nipase sise eyi ni litiresg se le se ojuse re ki 6 si je olotiito si awujo re. Ernest Fischer fi ara mo ero wa yii pe bi owo-ori se je dandan, ti aso jbora si je tulaasi, ni 6 pondandan fun litireso lati je olotiito nipa jije ise fun awujo re. Akangbe (2005:28) se amulo lati inu ise Fischer pe, In a decaying society, art, if it is truthful, must also reflect decay. And unless it wants to break tradition with its social function, it must show the world as changeable, and helps to change it. Bi ise ona yoo ba se oloooto, 6 gbodo se afihan awujo ti 6 ri jera gege bi eyi ti 6 ri dibaje. Bi ko ba ni tapa si ojuse re si awujo, 6 gbodo safihan aye gege bi eyi ti 6 se e yipada, ki 6 si sa apa lati yi i pada. Nitori naa, 6 di dandan ki ise ona se afihan awujo gele bi 6 ba ti ri. Se bi oju ba ri se ipin, a maa n yo 6 han oju ni pe 6 n se aidara. Bi awujo ba n dibaje, ise ona gbodo fi idibaje re han; bi 6 ba si n tuba-tuse, ti 6 si peye, ise ona gbodo fi ipeye ati ikun-oju- osuwon re han bakan naa gege. Iyapa Ise Fagunwa si Alp Pelu atotonu wonyi, a ti fi idi era wa mule pe ijora ti n be laarin alo ati ise Fagunwa kii se keremi. Ni otito ni eyi ri bee, amo a ko le salai ri awon iyapa kopkan toka si. Iyapa ti 6 hande ju si alo ni ggbon ayaba tabi fitansotan ti Fagunwa 16. Eyi ni sise amulo itan ninu itan lati le mu ki itan feju. 116 ayaba bawonyi a maa fun onkowe ni anfaani lati se afikun ti 6 ba ni lokan amo ti 6 nira fun un lati gbe wo inu ojulowo itan. 116 ayaba yii je Fagunwa logun tori pe awon ni 6 so ise re ro. Ogbon ayaba yii a maa fun Fagunwa ni anfaani lati se iwaasu, ki 6 si so itan orisiirisii pelu sugbon ajeji ni ilo ayaba je si alo. Alo a maa ni opo itan ti 6 gun ti 6 si Ip taara. Alo kii ya sigbo ya siju; san-an laa rin ni oro tire amo eyi ko ri bee ninu awon itan aroso Fagunwa ninu eyi ti ppplopp ayaba wa. Ete ilo ayaba wonyi ni lati le je ki itan re kun. Ede tun je orisun iyapa ise Fagunwa miiran si alo. Ede geere, ede san-an, ede pmode pelu ni ti alo. Se ika ti 6 ba to si imu ni a fi i re e, ede ti 6 to si awon pmode ti a maa n fi alo ko logbon naa ni a maa n 16. $e alo ni tgmgde owe ni tawon agba, a ko le se amulo ede ti 6 ki fun alo tori ki 6 le ye awon olugbp. Tori naa, ede sanponna ni ti alo sugbon eyi ko ri bee ninu iwe Fagunwa. Ede Fagunwa ki i se ede ewe tabi ti ogberi rara, ede re kun, 6 ki, 6 si loyin pelu. Ede re ki i se ede arobo tabi awose, ede abiloje ti o mg awo i se ni. $e aisprpyanro ni 6 pa Elenpe isaaju( bi a ba ri ona kan tabi meji ti ise Fagunwa fi yato sî alo, amo niyen ko mo ara eran. Idi ni pe Fagunwa ki i kuku se apaalo tabi asotan. Onkowe litireso alatinuda Yoruba ni. Ise litireso si pe fun atinuda, arogun, ipalaro ati asodun. Otun otun ni ojpp yo, otun otun ni oorun i ran, otun otun naa ni ironu onise ona litireso. Ise litireso gbodo rewa, ki 6 to di pe 6 yege, onkowe ko si gbodo kaaare lati pese eroja ewa wonyi; aije bee, awo re yoo sun ni ebi. Orisirisi ona ni ewa le 337 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY gba waye. Ewa le waye lati ipase ede, agbekale itan, eda itan ati koko itan pelu. Fagunwa mo idf abajo wonyf ko si kaaare lati se amulo won bf 6 ti to ati bf 6 ti ye. O mo isin je, 6 si mo iku oju re yan. idf niyf tf a fi sp pe 6 kan se amulo batani alo kf ise re le munadoko ni, kif se pe 6 kuku n pa alo, a ko si gbodo retf kf ise re je alo gele. Agbalogbabo Nf akotan, ko ye kf a kadif pro laigbe dsuba eye fun Fagunwa. Yato sf pe 6 fi apeere ise aseyori lele gege bf akoni onkowe, awon ise wonyf kun fun iwaasu ati imoran tf 6 le mu ona omp eda gun kf aye re si toro. Boya ni a si le rf omfran nfnu iwe itan aroso Yoruba tf 6 se akopo aimoye eko gege bf a ti rf i nfnu awon iwe Fagunwa. iwe itokasi Abimboia, W. (1965). "Yoruba Oral Literature", African Notes, Vol. 2, Nos. 2-3, pp. 1 - 4. Adejumo, A. (2011). "Text and Inter-textuality in contemporary Yoruba Literary works" in Falola and Oyebade (eds.). Yoruba Fiction, Orature, and Culture. Trenton: Africa World Press. Akangbe C.A. (2005). "From the Stage to Motion Pictures: The Changing Phases of Lere Pafmo Theatre." An Unpublished Master of Arts Project in the Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Ibadan. Adeleke, D. (2011). Leyin Itan Aroso Fagunwa Maraarun, Ewo id Ax)? Ibadan: DB Martoy Books. Alaba A. ati Ogunsfpe (1982). iwe afinimona ion awon iwe Fagunwa. Ikeja: Thomas Nelson (Nigeria) Ltd. Bamgbose, A. (1974). The Novels of D.O. Fagunwa. Benin-City: Ethiope Publishing Corporation. Fagunwa, D.O. (1938). Ogboju Ode Nfnu Igbo Irunmaie. Ikeja: Thomas Nelson and Sons Ltd. Fagunwa D.O. (1949). Igbo Oiodumare. Ikeja: Thomas Nelson and Sons Ltd. Fagunwa, D.O. (1949). ireke Onfbudo. Ikeja: Thomas Nelson and Sons Ltd. Fagunwa D.O. (1954). irinkerindd Nfnu Igbo Eiegbeje. Ikeja: Thomas Nelson and Sons Ltd. Fagunwa D.O. (1961). Adiitu Oiodumare. Ikeja: Thomas Nelson and Sons Ltd. Haberer, A. (2007). Intertextuaiity in Theory and Practice. Literatura 49(5). Humanities.wisc.edu/assets/misc/what_is_intertextuality.pdf. Accessed Thursday 28th July, 2016. Irele, A. (1975). "Tradition and the Yoruba Writer: D.O. Fagunwa, Amos Tutuola and Wole Soyinka" in Odu-A Journal of West African Studies, University of Ife, New series, No 11. Kristeva, J. (1966). The Kristeva Reader. Torill Moi (ed.). Oxford: Blackwe. Kristeva, J. (1967). "Bakhtine, le mot, le dialogue et le roman." Paris: Critique, (33,239) 438 - 465. Ogundeji, P.A. (1991). ifaara sf Litireso Alohun Yoruba. Ibadan: Ibadan External Studies Programme. Olatunji, O. (1984). Features of Yoruba Ora! Poetry. Ibadan: University Press Ltd. 338 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY Olunlade, T.A. (1999). "Agbeyewo Eewo Ni'nu Asayan Oriki ati Orile Yoruba", Unpublished M.A. Thesis, Dept of African Languages and Literatures, Obafemi Awolowo Universitiy, Ile-Ife. Qpadotun, O. (1994). Asayan Aid Om'tan. Ibadan: Y-Books. Soyinka, W. (1976): Myth, Literature and the African World. Cambridge University Press, Cambridge. Taiwo, 0. (1967): An Introduction to West African Literature. London: Oxford University Press. 339 UNIV ERSIT Y O F IB ADAN L IB RARY